Datasets:

Modalities:
Text
Formats:
csv
Size:
< 1K
ArXiv:
Libraries:
Datasets
pandas
License:
Dataset Viewer
Auto-converted to Parquet
language
string
goal
string
solution0
string
solution1
string
label
int64
Yoruba
Báwo ni mo ṣe le kó erè oko bíi ọsàn àti àgbàdo dé ilé láti oko?
Mo lè lo apẹ̀rẹ̀
Mo lè lo aṣọ ìbora
0
Yoruba
Ìka wo ni wọ́n maá ń fi òrùka ìgbéyàwó sí?
òrùká yẹmí ní ọwọ́ òsì
òrùká yẹmí ní ọwọ́ ọ̀tún
0
Yoruba
Kíni a fi ń d́á iná àsè
igi tó gbẹ la fi maá n dá iná àsè
ewé tútù la fi maá n dá iná àsè
0
Yoruba
kíni ìyá má fi ń gbé ọmọ pọ́n?
ìró àti okùn ni ìyá fi ń gbé ọmọ pọ́n
iro ati ọjà ni ìyá má fi ń gbé ọmọ pọ́n
1
Yoruba
Kíni a fi ń da ẹja lójú kó má bà tete bájẹ
Ata la fi ń da ẹja lójú kó má bà tete bájẹ
Iyọ̀ la fi ń da ẹja lójú kó má bà tete bájẹ
1
Yoruba
ọ̀nà tó tọ́ wo la maá ń gbà kí asọ fi gbẹ?
fún asọ daádaa kí o sá sí òrùn
fún asọ daádaa kí o sá sí inú ilé
0
Yoruba
Kíni àwọn àgbẹ̀ fi maá ń kó ewé tàbí koríko papọ̀?
wón maá ń lo ọkọ́ fi kó ewé tàbí koríko papọ̀
wón maá ń lo réèkì fi kó ewé tàbí koríko papọ̀
1
Yoruba
Ọ̀nà wo la fí maá ń gba omi òjò
gbígbé igbá sí abẹ́ òrùlé
gbígbé apẹ̀rẹ̀ sí abẹ́ òrùlé
0
Yoruba
Tí o bá fẹ́ se ìlu bàtá tí́ o dára, irú igi wo ni ó yẹ kí o lò ́
Igi líle bi mahogany tàbí ìrókò ni a fí ń se ìlu bàtá tí ó dára
Igi rírọ̀ bi pine tàbí́ balsa ni a fí ń se ì̀lu bàtá tí ó dára
0
Yoruba
Ni ìlu bàtá, èwo ni ótobi jùlọ?
Ìyá ìlù ni ó tóbi jùlọ nínu àwọn ìlu bàtá
ọ̀mélé ni ó tóbi jùlọ nínú àwọn ìlu bàtá
0
Yoruba
kíni a maá ń fi sé àdirẹ
a maá ń fi asọ àti ọsẹ sé àdirẹ
a maá ń fi asọ àti aró sé àdirẹ
1
Yoruba
kíni ó yẹ ká fi sí ewédú kó lè yọ̀ fùn jìjà daádaa?
o yẹ ká fi kán-ún sí i
o yẹ ká fi epo pupa sí i
0
Yoruba
Iru ilẹ̀ wo lo dára jùlọ fún kíkó ilé tó maa duro pẹ́?
ilẹ̀ amọ̀ ni a le fi kọ iru ile bẹ́ẹ̀
iyẹ̀pẹ̀ iyanrìn ni a le fi kọ iru ile bẹ́ẹ̀
0
Yoruba
Kí ni a maá ń fi sí àdìrẹ ̀abí ànkárá ta báa ń fọ̀ kí àwọ̀ rè má bà tètè parẹ́
a máa ń fi iyọ̀ sí ànkárá àti àdìrẹ ta báa ń fọọ kí àwọ̀ rè má báa tètè parẹ́
a máa ń fi kikan sí ànkárá àti àdìrẹ ta báa ń fọọ kí àwọ̀ rè má bàa tètè parẹ́
0
Yoruba
Kí ló máa ń ṣẹlẹ̀ sí àsìá tí afẹ́fẹ́ bá fẹ́ lágbára?
ó máa n mì tàbí kí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ já láti ara igi
ó máa n dúró ṣinṣin, kò sì ní mì rárá
0
Yoruba
Níbo ni àsìá máa ń kọ sí nígbà tí afẹ́fẹ́ ń fẹ́?
Àsìá máa ń kọ sí ibi tí afẹ́fẹ́ ń lọ sí
Àsìá máa ń kọ sí ibi tí afẹ́fẹ́ ti wá.
0
Yoruba
Kí ló máa ń ṣẹlẹ̀ sí omi tí a bá fi sínú ẹ̀rọ amóhuntutù?
Omi náà yóò di yìnyín
Omi náà yóò di gbígbóná
0
Yoruba
kíni ó yẹ kí ènìyaǹ fi wé ọrùn rẹ ní ìgbà òtútù?
aṣọ ìnujú
aṣọ òkè/ aṣọ ìborùn
1
Yoruba
kíni ohun tó dára jùlọ lati fi lẹ àwo tó fọ́ sí méjì?
lẹ àwo náà pọ̀ pẹ̀lú èedú
lẹ àwo náà pọ̀ pẹ̀lú òǹlẹ̀
1
Yoruba
láti fọ aṣọ tó dọ̀tí
mo lè lo ọṣẹ Ìfọṣọ
mo lè lo aró
0
Yoruba
O fẹ́ ṣe ibi ìsáṣọsi ní ẹ̀yìnkùnlé rẹ, kíni ohun elo tó dáa jùlọ?
Na okùn gígùn kan láàrín ọ̀pá méjì, kí o sì só ṣinṣin.
Na òwú gígùn kan láàrín ọ̀pá méjì, kí o sì só ṣinṣin.
0
Yoruba
Tí o ba fẹ́ ọ̀bẹ tí ó mú, kíni ó yẹ kí o ṣe
lo òkuta láti fi pọ́n ẹnu ọ̀bẹ náà
lo páálí láti fi pọ́n ẹnu ọ̀bẹ náà
0
Yoruba
Tí a bá fẹ́ ya irun ọmọ kékeré
ó dára kí a farabalẹ̀ ya irun na pẹ̀lú àmúga.
ó dára kí a farabalẹ̀ ya irun na pẹ̀lú òǹyà
1
Yoruba
Láti dín dídán ojú re kù ṣáaju yìya foto, ó da kí o
fi èérú pa ojú àti ẹkẹ́ rẹ fẹ́rẹ́fẹ́
fi àtíkè pa ojú àti ẹkẹ́ rẹ fẹ́rẹ́fẹ́
1
Yoruba
Lẹ́yìn tí o bá lò ọ̀bẹ ní ilé ìdáná, kí ni ó yẹ kí o ṣe?
fọ̀ ọ́ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ kí o sì fi sí ilẹ̀
fọ̀ ọ́ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ kí o sì fi pamọ́
1
Yoruba
Àwọn èròjà tí a lè fi sínu ewédú ni
káún, iyọ̀, irú
káún, iyọ̀, aró
0
Yoruba
Láti fọ ọwọ́ rẹ lẹ́yìn tí o bá dáná tán
fi ọṣẹ ra ọwọ́ rẹ, kí o sì fi omi tí ó mọ́ saǹ-án
fi àtíke ra ọwọ́ rẹ, kí o sì fi omi tí ó mọ́ saǹ-án
0
Yoruba
Láti tukọ̀ ọkọ̀ ojú omi kékeré
a lè lo òbèlè
a lè lo ọ̀pá
0
Yoruba
Ọ̀nà wo ló dára jù láti kọ́ ọmọdé láti ya òbìrìkìtì?
lo ìderí ìgò róbótó láti fi tọ sọ́nà
lo ìderí ìgò onígun mẹrin láti fi tọ sọ́nà
0
Yoruba
Nígbà tí ènìà bá fẹ́ kun ilé, ó dáa láti
tẹ́ ìwé ìròyìn sí abẹ́ ibi tí ó fẹ́ kun
tẹ́ ìwé ìfúniláyè sí abẹ́ ibi tí ó fẹ́ kun
0
Yoruba
Láti fọ àwọn aṣọ ìbora tí ó dọ̀tí,
kó wọn sínu ẹ̀rọ ìfọṣọ, kí o da ọṣẹ àti omi sì i, kí o sì tanná si.
kó wọn sínu ẹ̀rọ ìlọta, kí o da ọṣẹ àti omi sì i, kí o sì tanná si.
0
Yoruba
Kíni ohun tí a tún lè fi pọ́n ẹ̀bà nígbà tí kò bá sí ìgbákọ?
a lè lo fìlà
a lè lo síbí
1
Yoruba
Nígbà to bá tan ẹ̀rọ amúlétutù, ó yẹ kí o
sí gbogbo fèrèsé àti ilẹ̀kùn
ti gbogbo fèrèsé àti ilẹ̀kùn
1
Yoruba
Kíni ohun tí ó tọ́ láti ṣe tí ago ọwọ́ rẹ kò bá ṣiṣẹ́?
Mú bátìrì àtijọ́ jáde kí o fì bátìrì tuntun síi.
Mú bátìrì àtijọ́ jáde kí o fì bọ́tìnì tuntun síi.
0
Yoruba
kíni ó yẹ kí́ o ṣe lẹ́yìn tí o ba lo ẹ̀ro agbálẹ?
pa á, kí o sì tọju rẹ̀ sí ibi tí ó pamọ́
pa á, kí o sì tọju rẹ̀ sí ibi tí ó ṣí sílẹ̀
0
Yoruba
àgbétẹ́lẹ̀ tí o dára ju nígbà tí à bá fẹ́ lo ẹ̀rọ agbáwòrányọ ni
ògiri funfun kan
ògiri dúdú kan
0
Yoruba
agbóhùnsáfẹ́fẹ́ rẹ ko ṣiṣẹ́, kíni kí o kọ́kọ́ ṣe?
ríi dájú pé bọ́tìnì agbára tí wà ní títàn
ríi dájú pé bọ́tìnì ìdádúró tí wà ní títàn
0
Yoruba
Kíni a lè fi rán ṣòkòtò tí o ya?
Abẹ́ẹ́rẹ́ àti òwú
Abẹ́ẹ́rẹ́ àti okùn
0
Yoruba
Kíni ohun èlò tí ó dára jùlọ láti rẹ́ ata rodo?
àdá tí ó mú daadaa
ọ̀bẹ tí ó mú daadaa
1
Yoruba
Tí mo bá fẹ mọ̀ bí iṣú bá tí jiná,
mo ma fi àmúga ṣàyẹ̀wò bóyá ó ti rọ̀
mo ma mi ìkòkò lati wò bóyá ó ti rọ̀
0
Yoruba
Tí ọ̀nà ọ̀fun rẹ bá n dun ọ, kí ni o lè ṣe?
po omi gbọ́na pèlú oyin àti òrònbó kíkan, kí o sì mu ú
po omi gbọ́na pèlú àádùn àti òrònbó kíkan, kí o sì mu ú
0
Yoruba
Ẹ̀yà ara wo ni ko yẹ kí o fi ọwọ́ kan lẹ́yìn ti o ba lọ/rẹ́ ata?
kò yẹ kí o fọwọ́kan ojú rẹ
kò yẹ kí o fọwọ́kan ọwọ́ rẹ
0
Yoruba
Kíni o lè lo rọ́pọ̀ ọmọ ayò nígba tí o bá ń tá ayò ọlọ́pọ́n
Lo àwọn òkuta wẹ́wẹ́
Lo àwọn òkuta tí o tóbi
0
Yoruba
Kini ọna ailewu lati bọ́ lẹ̀ kuro ninu ọkọ òfurufú lẹ́hìn tí o bá balẹ̀?
Dìde lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, gbé àpò rẹ, kí o si sáré jade
Ṣe sùúrù, kí o si rọra tèlé ìlànà
1
Yoruba
Tí ìṣó ba n yọ lára tabili rẹ,
fi ìkànṣo lù ú padà sínu tabili
fi ṣíbí lù ú padà sínu tabili
0
Yoruba
O ṣèṣẹ fọ aṣọ ibọsẹ re, o sì fẹ́ kí ó tètè gbẹ
sá a sí óòrun titi yóò fi gbẹ.
fi sínu àpò ilé-ìwé rẹ titi yóò fi gbẹ.
0
Yoruba
O fẹ lo agbóhùnsáfẹ́fẹ́ rẹ ni ita láì dàmú àwọn aladugbo
Dín ìwọ̀n dídún si ipele kékeré
Dín ìwọ̀n dídún si ipele gíga
0
Yoruba
Ọ̀pá omi kan ń jò ní ilé ìdana rẹ
fi tìmùtìmù dí ibi ti ó ń jò náà
fi téèpù wé ibi ti ó ń jò náà
1
Yoruba
Kíni ọ̀nà tí ó dára jùlọ láti gbé ibùsùn ti o wúwo
gbé sókè pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ ẹlòmíràn
gbé sókè pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ igi ìgbálẹ̀
0
Yoruba
Ḱíni ó yẹ kí o ṣe lẹyìn tí o bá gé àlùbọ́sà?
fọ ọwọ́ rẹ pẹ̀lú ọṣẹ àti omi
fọ ọwọ́ rẹ pẹ̀lú epo àti omi
0
Yoruba
O fẹ́ tọ́ju oúnjẹ sínu ẹ̀rọ amóhuntutù
jẹ́ kí oúnjẹ náà tutù kí o tó fi sínu ẹ̀rọ amóhuntutù
fi oúnjẹ gbígbóná tààrà sínu ẹ̀rọ amóhuntutù
0
Yoruba
Lati wọn ìyẹ̀fun tí o tọ́ fun àkàrà òyínbó
lo òǹwọ̀n lati wọn ìyẹ̀fùn tí ó péye
lo okùn ìwọnṣọ lati wọn ìyẹ̀fùn tí ó péye
0
Yoruba
Kí ni ọ̀nà tó dára jù lati mọ̀ bí epo ba ti gbóna tó nígbà to bá ń dín àkàrà
bu omi díẹ̀ sínu epo
bu àkàrà díẹ̀ sìnu epo
1
Yoruba
Irú aṣọ wo ni o yẹ lati fi nu àwo oju rẹ
Aṣo ìnulẹ̀
Aṣọ ìnujú
1
Yoruba
Lati mo bii ẹ̀rọ ìlọṣọ ba ti gbona to fún lílò
Gbé ojú ẹ̀ro náà sí orí aṣọ díẹ̀ lati fi dán-an wò
Gbé ojú ẹ̀ro náà sí àtẹlẹwọ rẹ lati fi dán-an wò
0
Yoruba
Ò fẹ gbin àgbado ni ẹ̀yìnkunlé rẹ, ohun èlò wo ni ó dára ju lati fi wa ihò?
Lo ọkọ́ lati fi walẹ̀
lo ìderí ìgò lati fi walẹ̀
0
Yoruba
Bawo ni o ṣe lè nu ẹrẹ̀ kúrò lára bàtà rẹ?
fi omi ṣan ẹrẹ̀ naa kuro
fi ọwọ nu ẹrẹ̀ náà kurò
0
Yoruba
Lati se ẹyin, èwo nínú àwọn ìgbésẹ̀ wọ̀nyí ni ó yẹ kí o tẹ̀le?
fi ẹyin sínu omi, gbé e ka ná, sì jẹ́ kí o se fun bi ìṣẹjú mẹ́wàá
fi ẹyin sínu òroró, gbé e ka ná, sì jẹ́ kí o se fun bi ìṣẹjú mẹ́wàá
0
Yoruba
Ki ni o le ṣe nígbà tí ìdọ̀tí bá kó sí ọ ní ojú?
mo lè̀ fi ọwọ́ mímọ́ gbo ojú mi
mo lè̀ fi omi mímọ́ ṣan ojú mi
1
Yoruba
Lati di ṣíbí mu, ó yẹ kí n
lo ọwọ́ mi
lo ẹsẹ̀ mi
0
Yoruba
Tí o ba fẹ́ gún iyán, kíni ó yẹ kí o kọ́kọ́ ṣe?
Bẹ iṣu náà kí o sì sè é
Bẹ iṣu náà kí o sì gun láì sè é
0
Yoruba
Láti lè mọ̀ bóyá ìbẹ́pẹ ti pọ́n?
Rọra tẹ awọ ara ìbẹ́pe náà
Rọra fi ìṣó gún ìbẹ́pẹ náà
0
Yoruba
Tí o ba fẹ́ jẹ ìbẹ́pẹ, kíni ó yẹ kí o kọ́kọ́ ṣe?
Fí omi ṣan ìbẹ́pẹ náà kí o tó jẹ
Fi aṣọ nu ìbẹ́pẹ náà kí o tó jẹ
0
Yoruba
kí ni o le ṣe lati jẹ́ kí òórùn ẹja kúrò ní ọwọ́ rẹ?
fí epo ra ọwọ́ rẹ, kí o sì sàn-án
fí ọsàn wẹ́wẹ́ ra ọwọ́ rẹ, kí o sì sàn-án
1
Yoruba
Mo lè fi omi àgbọn
fọ aṣọ ìbora mi
se ìrẹsì alagbọn
1
Yoruba
Kí ni o le ṣe lati jẹ ki ọ̀gẹ̀dè dòdò pọ́n kíákíá?
tọ́jú rẹ sí inú ẹ̀rọ amóhuntutù mọ́jú
tọ́jú rẹ sí ibi tí ó mú ooru mọ́jú
1
Yoruba
Lára àwọn èròjà fún ọ̀lẹ̀lẹ̀ ni?
ẹ̀wà, ata, iyọ, epo pupa, edé
ẹ̀wà, ata, iyọ, kaúń, edé
0
Yoruba
Bawo ni o ṣe lè fo ònà lailewu?
Wò bi ọkọ̀ ba n bọ kí o to fònà
Di ojú rẹ kí o to fònà
0
Yoruba
Ibo ni o lè tọ́jú ago ọwọ́ rẹ sí?
Inu ìkòkò ìdáná
Obì ni ó dára jùlọ ní èròjà
1
Yoruba
Nígbà tí a bá fẹ́ ṣe ọbẹ̀ olú,
Olú ni ó dára jùlọ ní èròjà
null
0
Yoruba
Tí a bá fẹ́ rí àwọn èèrà salámọ́
Inú yìnyín dìdì ni a máa wò
Inú òkìtì ọ̀gán ni a máa wò
1
Yoruba
Ilẹ̀kùn ilé tí a fi àgádágodo tì pa
Ìṣó ni ó lè sí i pẹ̀lú ìrọ̀rùn
Kọ́kọ́rọ́ ni ó lè sí i pẹ̀lú ìrọ̀rùn
1
Yoruba
Kí ni mo lè fi ti ilẹ̀kùn ilé mi pa?
Kọ́kọ́rọ́ ni mo lè lo láti ti ilẹ̀kùn mi pa
Àgádágodo ni mo le lò láti fi ti ilẹ̀kùn mi pa.
1
Yoruba
Kí ni àwọn ọmọ òkú máa ń jẹ́ lẹ́yìn ikú òbí wọn?
Ogún ni àwọn ọmọ òkú máa ń jẹ́
Àmàlà ni àwọn ọmọ òkú máa ń jẹ
0
Yoruba
Tí ará mi kò bá yá, kí ni mo ma lò?
Oúnjẹ ní mo ma lò
Ògùn ni mo ma lò
1
Yoruba
Tí omi ìrẹ̀sí kò bá gbẹ́ ní orí iná
A máa da ìrẹsì sínú àpò láti sẹ́ ẹ
A máa da ìrẹsì sínú asẹ́ láti ṣẹ́ ẹ
1
Yoruba
Kí ni nǹkan tí ènìyàn máa wò láti rí ara rẹ̀ nígbà tí ó bá múra tán?
Dígí ni ènìyàn máa wò
Ògiri ni ènìyàn máa wò
0
Yoruba
Láti pèsè Àmàlà fún oúnjẹ
A nílò ọmọrogùn
A nílò ìjábẹ̀
0
Yoruba
Níbo ni àyè tí ó wà láàárín apá sí èjìká?
Ọrùn-ọwọ́ ni àyè tí ó wà láàárín apá sí èjìká
Ìgùnpá ni àyè tí ó wà láàárín apá sí èjìká
1
Yoruba
Nígbà tí mo bá fẹ́ kọ lẹ́tà, kí ni mo ma lò?
Gègé ni mo máa lò láti kọ lẹ́tà
Ẹfun ni mo máa lò láti kọ lẹ́tà
0
Yoruba
Irú ilé wo ni a kọ́ sórí ara wọn?
Ahéré ni ilé tí a kọ sórí ara wọn
Ilé-alájà tàbí pẹ̀tẹsì ni ilé tí a kọ́ sórí ara wọn
1
Yoruba
Tí mo bá fẹ́ dìbò, ìka wo ni màá lò?
Àtàǹpàkò ni ìka tí ó yẹ láti dìbò
Ìka àárín ni ó yẹ láti dìbò
0
Yoruba
Nígbà tí òrùlé ilé mi bá ń jò
Màá gun igi láti lọ yẹ̀ ẹ́ wò
Màá gun àtẹ̀gùn láti lọ yẹ̀ ẹ́ wò
1
Yoruba
Tí ọtí bá ń wù ẹ́ mu
Lo igbá láti mú ọtí
Lo apẹ̀rẹ̀ láti mu ọtí
0
Yoruba
Àwọn alábàárù tí kò bá lo abọ́ láti ko ẹrù
Wọ́n máa lo ife
Wọ́n máa ọmọlanke
1
Yoruba
Lára nǹkan Ọ̀ṣọ́ ni
Páńda náà wà
Wúrà náà wà
1
Yoruba
Kí ni alágbẹ̀dẹ le lò láti rọ ohun èlò onídẹ?
Idẹ ni alágbẹ̀dẹ le lò láti rọ ohun èlò onídẹ
Ẹ̀mú ni alágbẹ̀dẹ le lò láti rọ ohun èlò onídẹ
0
Yoruba
Kí ni ará nǹkan tí alágbẹ̀dẹ fí máa ṣe ohun èlò ọ̀ṣọ́?
Owú ni ara nǹkan tí alágbẹ̀dẹ fí máa ṣe ohun èlò ọ̀ṣọ́
Òjé ni ara nǹkan tí alágbẹ̀dẹ fí máa ṣe ohun èlò ọ̀ṣọ́
1
Yoruba
Tí mo bá fẹ́ nǹkan olówó iyebíye yàtọ̀ sí wúrà
Fàdákà ni màá yàn láàyò
Òkúta ni màá yàn láàyò
0
Yoruba
Torí kí ni wọ́n máa ń sun igi ńláǹlà níná
Nítorí èédú ni wọ́n ṣe máa ń sún igi ńláǹlà níná
Nítorí éérú ni wọ́n ṣe máa ń sún igi ńláǹlà níná
0
Yoruba
Kí ni nǹkan mìíràn tí a tún le ri lára epo rọ̀bì?
Epo pupa ni nǹkan mìíràn tí a tún lè rí lára bẹntiró
epo bẹntiró ni nǹkan mìíràn tí a tún lè rí lára bẹntiró
1
Yoruba
Tí mo bá fẹ́ kí ilé mi tuntun rẹwà ní àwọ̀
Màá lo ọ̀dà tí ó rẹwà
Màá lo ìyèpẹ̀ tí ó rẹ̀wà
0
Yoruba
Lára ibo ni a ti le rí epo òyìnbó
Lára epo rọ̀bì ni a ti le rí epo òyìnbó
Lára ẹyìn ọ̀pẹ́ ni a ti le rí epo òyìnbó
0
Yoruba
Kí tún ni a lè fi ṣe ìkòkò ìdáná lẹ́yìn amọ̀?
Òkúta ni a tún le fi ṣe ìkòkò ìdáná lẹ́yìn amọ̀
Irin ni a tún le fi ṣe ìkòkò ìdáná lẹ́yìn amọ̀
1
Yoruba
Tí ó bá fẹ́ sọdá odò sí òdìkejì
Gun orí pákó kọjá
Gun orí àfárá kọjá
1
Yoruba
Kíni màá fi nu omi tí ó dà sílẹ̀ nínú ilé?
Aṣọ inùlẹ̀ tí ó gbẹ́ ní màá lò
Aṣọ ìwọ̀sùn tí ó gbẹ́ ní màá lò
0
Yoruba
Láti mú kí aṣọ fífọ̀ mi yá kíákíá, kí ni mo le lò?
ẹ̀rọ ìfọbọ
ẹ̀rọ ìfọṣọ
1
Yoruba
Kí ni ọ̀kan pàtàkì lára irinṣẹ́ aránṣọ?
Ọmọrogùn jẹ ọ̀kan pàtàkì lára irinṣẹ́ aránṣọ
Abẹ́rẹ́ jẹ́ ọ̀kan pàtàkì lára irinṣẹ́ aránṣọ
1
Yoruba
Kí ni wọ́n fi ń ṣe gààrí?
Gbágùúdá/ẹ̀gẹ́ ni wọ́n fi ń ṣe gààrí
Ọ̀pẹ̀-òyìnbó ni wọ́n fi ń ṣe gààrí
0
Yoruba
Tí apẹja bá fẹ́ mú ẹja lódò, kí ni yóò lò?
Pàkúté ni apẹja yóò lò láti mú ẹja lódò
Àwọ̀n ni apẹja yóò lò láti mú ẹja lódò
1
End of preview. Expand in Data Studio

Physical Commonsense Reasoning for Yorùbá and Nigerian Pidgin

Dataset Summary

This dataset was developed for the MRL 2025 Shared Task on Multilingual Physical Reasoning. For more details, see Global PIQA: Evaluating Physical Commonsense Reasoning Across 100+ Languages and Cultures.

It provides a test collection for evaluating physical commonsense reasoning, that is, a model's ability to understand how objects, actions, and outcomes relate in everyday scenarios.

The dataset covers two West African languages: Yorùbá and Nigerian Pidgin, containing culturally grounded instances created and reviewed entirely by native speakers.

Dataset Structure

Data Instances

Example from Yoruba:

{
  "goal": "Tí mo bá fẹ́ dìbò, ìka wo ni màá lò?",
  "sol0": "Àtàǹpàkò ni ìka tí ó yẹ láti dìbò",
  "sol1": "Ìka àárín ni ó yẹ láti dìbò",
  "label": 0
}

Data Fields

  • goal: the objective or question in Yorùbá or Nigerian Pidgin
  • sol0: first solution candidate
  • sol1: second solution candidate
  • label: index of the correct solution (0 or 1)

Dataset Creation

All instances were created from scratch by native speakers using a systematic three-step approach:

  1. Reference Collection: Collected a list of reference objects and activities from diverse, publicly available sources, including language dictionaries, YouTube videos, and social media platforms (e.g., X, Facebook).

  2. Scenario Development: Created realistic, culturally grounded scenarios for each compiled object or activity.

  3. Instance Structuring & Annotation: Each scenario was framed as a practical goal accompanied by two candidate solutions (solution0 and solution1), with the correct solution annotated in the label field.

Downloads last month
7